Page 2
The Islamic Bulletin
The Purpose Of Life
Ni awon ese ti a ka loke yi, Allah so fun
yeke, ni akoko nipa fi fa okan wa si dida wa gegebi
eniyan. Orisi eya eniyan ati orisi iwa awon eniyan.
O fa okan wa si awon orun. Iyipada larin ojo ati
oru. Ofurufu, awon irawo, awosanmo… O si so
fun wa wipe oun ko da awon nkan wonyi lai nidi!
Nitori ni igba ti o ba wo igbekale won, wa a ri wipe
igbekale naa dara o si gun rege o si ju isiro ati imo
wa lo – ko le je lasan. Ko kan le wa lasan.
Fun apeere, ti o ba mu okuta mewa ti o si
ko onka si ori won lati okan de ori mewa. Ti gbog-
bo won si je orisi awo ti o yato sira won. Ti o ba ko
won si inu apo ti o si mi apo naa papo. Ki o wa di
oju re, ki o fi owo si inu apo naa, “ki o wa maa mu
awon okuta naa jade leyo Kankan ni sise ntele lati
ori akoko titi de ori ikewa.” Bawo ni o sese si fun o
lati mu awon okuta naa jade ni sise ntele? Nje o mo
bi o seese si? Milionu mefa si okan! Nitorina, kini
anfaniboya o seese pe orun ati aye yi kan waye be,
ki won si wa ni pipe bi won se wayi? Kini aye fun
eyi?
Eyin olugbo ati alejo mi owon – a ni lati
bere ibeere kan si l’owo ara wa… Ni igba ti o ba ri
afara, ile, tabi oko – dajudaju wa ro nipa eni tabi
ile-ise to se e. Ni igba ti o ba ri oko ofurufu, roketi,
satelaiti, tabi oko oju omi nla – wa tun ro bakanna
nipa bi oko naa se tobi to. Nigba ti o ba ri ile ohun
elo iparun, ibudoko oko ofurufu pelu gbogbo awon
ohun elo ti o nbe nibe, bakanna ti iwo ba ro nipa
awon ohun meremere ni ihin, ni orile-ede yi – yi o
je ohun iwuri fun o awon imo ero ijinle ti a ti fi se
awon nkan wonyi.
Be, awon wonyi je awon nkan ti a aseda lati
owo awon omo eniyan. Bawo ni ara eniyan pelu
gbogbo eya re? Ro ni pa re! Ro nipa opolo--- bi o
ti n ronu, bi o ti n sise, fi alaye pamo, se iyato laarin
alaye laarin iseju aaya! Opolo ma n se awon nkan
wonyi ni gbogbo igba. Ro ni pa opolo fun igba die.
Eyi ni opolo to se awon oko, oko oju omi, oko oju
ofurufu ati bebelo. Ro nipa opolo ati eni ti o se. Ro
ni pa okan, bi o ti n sise pinpin eje lai simi fun ogota
tabi adorin odun – ni pinpin eje kaakiri gbogbo ara,
ati si se ise ni dede ti de opin ile aye eni naa. Ro ni
pa re! Ro ni pa awon kidirin – irufe ise ti won nse?
Eya ara ti o n se afomo gbogbo ago ara, ti o si mo
juto oye idoti tin be ninu ara. O ma nse eleyi fun ara
re. Ro ni pa awon oju re – ayaworan ara ti o n wo,
ti o nmu ti o si n se amulo awon awo orisirisi fun ara
re. Eyi ti o gba itana fun ara re. Ro nipa re – tani eni
o da iwonyi? Tani o pete re? Tani o pinle re? Tani on
se abojuto re? Awon eniyan fun ara won bi? Rara
Bawo ni agbaye yi? Ro ni pa eyi. Ile aye yi je
okan ninu awon isogbe-orun ninu eto oorun wa. Eto
oorun wa si je okan ninu awon eto ti o wa ni Milky
way. Milky Way si je okan ninu awon akojo irawo
ni galasi. Egberun lona egberun galasi ni o si wa. Ro
nipa eyi. Gbogbo won ni won si wa leto leto. Won
pe perepere. Won ko kolu ara won. Se awon eni-
yan ni won se eyi? Se awon eniyan ni o n mu oju to
won? Rara, ki se awon eniyan.
Ro nipa awon okun nla, awon eja, awon
kokoro, awon eye, awon ohun ogbin, awon kokoro
kekeke, awon kemika ti a ko I ti se awari ati ti a ko
tile le se awari won pelu imo ijinle wa. Bee, gbogbo
won ni won ni ofin ti won n tele. Nje gbogbo amu-
sisepo yi, eto yi, iyato yi, itoju yi, ati ailonka yi – nje
eyi waye lasan? Ati pe, se awon nkan wonyi n sise ni
pipe lasan? Se won si n seda ara won lasan? Rara, ki I
se be?
Lati ro bayi yi o je iwa ope ati ti omugo. Bi o
ti wu kori, ona kana yi o wu ti awon nkan wonyi gba
waye koja oye ati agbara eniyan. Gbogbo wa pata la
gba eyi. Eni ti ope ati iyin to si ni alagbara julo – Ol-
orun. Olorun ni o da gbogbo nkan wonyi, O n naa
ni o si n se abojuto won. Nitorina, Olorun nikan ni
gbogbo iyin ati ogo ye fun.
Ti mo ba fun enikankan yin ni ogorun dola,
lai ni di, wipe e kan wa si ihin lasan, o kere ju e o tile
so wipe “O seun.” Sugbon, wo oju re, awon kidirin
re, opolo re, emi re, imi inu re, awon omo re? Ro
nipa wonyi. Ta lo fun o ni iwonyi? Nje O ye fun iyi
ati ope re? Nje ko ye lati gba ijosin ati idanimo re?
Arakunrin mi ati Arbinrin mi, ni soki, eyi ni ere idi
iwalaye wa.
Allah so ninu Kurani:
“Atipe Emi ko se eda alijonu ati enia lasan ayafi ki
nwon le ma sin Mi.”
(Kuran 51: 56)