Page 6
The Islamic Bulletin
The Purpose Of Life
miran ti e tun gbodo fi sokan ni wipe Muhamadu
(PBUH), yato si awon ti won ti wa siwaju re – ko wa
si odo awon Arabu tabi awon eniyan re nikan. Rara…
Nitorina, Islam ki I se esin awon Arabu. Bo ti le je
wipe Anabi Muhamadu, omo Abdulahi, a bi ni Moka,
ilu ti o wa ni agbegbe Arabia, o si je Arabu, ko mu
Islam wa fun awon arabu nikan. O mu Islam wa fun
gbogbo eniyan.
Bo tile je wipe, a se afihan Kuran ni ede
larubawa, ko tumo si wipe ise iranse Muhamadu wa
fun awon ara Arabu nikan. Nunui Kuran mimo, Allah
so wipe,
“Atipe Awa ko wule ran o nise ayafi ki o le je ike fun
gbogbo aiye.”
[Kuran 21:107]
Anabi Muhamadu (Ki Alaafia Wa Pelu Re) so wipe:
Gbogbo eda eniyan wa lati odo Adamo ati Efa, ara Ara-
bu ko ni ase lori eni ti ki I se Arabu; beeni alawo funfun
ko ni ase lori alawo dudu yala alawo dudu lori alawo
funfun bikose nipa iwa pipe ati ise rere.
Ni idi eyi, Muhamadu (PBUH) je akotan ati
ade ori gbogbo awon anabi ati ojuse ti o ti siwaju re.
Opolopo awon eniyan—won ko mo nipa alaye yi.
Nitoripe mo n toka si Kurani lati se eri fun oro
mi, maa se alaye die nipa ipinlese Kurani fun ara re.
Ni akoko, Kuran so wipe ere ise ifihan ni ohun je. Eyi
ni wipe, a ran-an sokale wa lati odo Olorun Atobiju si
muhamadu fun imisi.
Allah so wipe,
“Atipe ki nso oro ife-inu.”
“On ko je kinikan bikose ise ti a ran (si I).”
[Kuran
53:3-4]
Muhamadu ko soro nipa ara re, ero re, ife re,
tabi edun re. Sugbon, eyi je ifihan ti a fi han-an! Eyi je
oro Allah. Nitorina, ti mo ba fe je ki e gba otito Kurani
gbo, mo ni lati je ki e mo – ni akoko, pe ko sese fun
muhamadu lati s’eda iwe bi iru eyi fun. Lona keji, mo
gbodo je ki e mo wipe ko seese fun eniyan k’eniyan
kan lati seda re. E je ki a ro nipa eyi.
Kuran so bayi wipe,
“Lehinna A see ni omi gbologbolo sinu aye irorun
Kan.”
[Kuran 23:13]
“O fi eje didi da enia.”
[Kuran 96:2]
Bawo ni anabi Muhamadu (pbuh) se mo pe
omo inu maa n bere gegebi eje ti o dipo ti o si so mo
ogiri inu ile omo iya re? Nje o ni ero irijin ni? Nje o ni
ero iwo omo inu? Nje o ni awon ero iya aworan egun-
gun ni? Bawo ni o se ni oye yi, oye ti o je wipe a sese
se awari re ni bi ogoji odun ole meje seyin?
Bakanna, bawo ni O se mo wipe awon odo
nla ni ipinya laarin won lati pin omi osa ati omi okun
soto?
“Atipe On ni Eniti O mu awon odo meji san, okan
dun ti odun gaan, ikeji ni iyo o si muro. O si fi gaga
si arin awon mejeji ti a fi di won mo.”
[Kuran 25:53]
Bawo ni o se mo eyi?