Page 7
The Islamic Bulletin
The Purpose Of Life
“On ni Eniti O da oru ati osan ati orun ati osupa. Olu-
kuluku won nluwe ninu ate (awowo).”
[Kuran 21:33]
Bawo ni o se mo pe Orun, Osupa ati awon aye
n we koja ni aye ti a ti pase sile fun won? Bawo ni o
se mo eyi? Ati bebelo- bawo ni o se mo awon nkan
wonyi? Awon kan wonyi sese di awari ni nkan bi ogun
odun le marun si ogbon odun seyin. Imo ero ati imo
ijinle, sese se awari nkan wonyi. Bawo ni Muhamad-
u(PBUH) , ti o gbe ni egberun odun kan ati abo sehin
– oluso aguntan eni ti ko kawe ti a to dagba ninu agin-
ju, ti ko le ko tabi ka-- bawo ni o se mo iru awon nkan
bayi? Bawo ni o se le se nkanbayi? Ati bawo ni enikeni
ti o gbe pelu re, siwaju re tabi lehin re, se le se nkan ti
o sese di awari laipeyi. Eyi ko seese! Bawo ni okunrin
kan ti ko kuro ni gbogbo agbegbe Arabia, okunrin kan
ti ko wo okooju omi ri, ti o gbe ni egberun odun kan
abo sehin –so iru kan bayi ti a sese se awari re ni aipe
yi?
Pelu, ti eyi ko ba to, je ki so fun yin pe Kuran ni
ori merin-leni adofa, o le ni egberun mefa ese. Ogo-
run awon eniyan ni o si wa ni igba Anabi Muhamadu
(ALAAFIA WA PELU RE) ti won ha gbogbo iwe naa
s’ori. Bawo ni eyi se sele? Nje o je akanda eniyan kan?
Nje enikeni ha iwe ihinrere s’ori – enikeni? Nje eni-
keni ha iwe ofin s’ori, Orin Dafidi, Majemu Lailai, ati
majemu Titun? Enikeni ko I ti se eyi. Popu papa ko I ti
se.
Sugbon egberun lona egberun awon Musulumi
lo wa loni ti won ti ha gbogbo iwe yi si ori. Eyi je ojuse
gbogbo Musulumi. Ki I se fun awon die – sugbon
gbogbo won! Kristiani melo ni e ti pade ti won ti ha
gbogbo Bibeli s’ori? Kosi. E ko ti I pade Kristiani Kank-
an ti o ti ha gbogbo Bibeli s’ori , nitori e ko I ti pade
Kristiani Kankan ti o mo ohun ti Bibeli wa nipa. Ki lo
fa eyi? Nitori, awon Kristiani fun ara won, won ni o le
ni edegberin orisirisi eya ijo, won si ni bi orisirisi eda
bibeli mokandilogoji—pelu orisirisi iwe. Orisirisi awon
ese ati orisirisi ori iwe. Won ko si si ni isokan. Nitorina,
bawo ni won se fe ha ohun ti won ko fimo sokan si
s’ori?
Eyi je awon die lara awon eri nipa Kuran. A si
ti pa Kuran mo lai si ayipada bo ti wu ko kere mo ni
opoplopo odun fun bi egberun odun kan ati abo se-
hin. Mi o soro lati da lebi. Mo ti je kristiani ri. Mo si se
iwadi awon ohun wonyi fun ara mi. Emi naa ni mo n
so awon nkan wonyi fun yin. Mo n si awon okuta kan
soke fun yin lati wo abe re. O kun si owo yin!
Kan ro nipa gbogbo wonyi boya won je otito.
Nje iwo yi o gba pe iwe yi je ogidi? Ati pe o je ara
oto? Nje iwo yi o se olotito lati so be? Ni otito iwo yio
so be, ti o ba je olotito. Iwo si je be. Ninu ara re, iwo
ti wa si ipinnu yi. Opolopo awon ti ki I se Musulumi
ni won ti wa si ipinnu bayi. Awon eniyan bi Benjamin
Franklin, Thomas Jefferson, Napoleon Bonaparte, ati
Winston Churchill, ki nkan ti d’aruko awon die. Opol-
opo si wa, mo si le tesiwaju lati maa daruko lo. Gbog-
bo won wa si ipinnu kanna. Boya won gba esin Islam
ni gbangba tabi rara. Won wa si ipinnu kan yi—pe ko
si iwe miran ni gbogbo agbaye yi ti o je ogidi bi kuran,
orisun imo ati iwosan ati itosana.
Nisiyi ti a ti yanju ifesemule Kuran, e je ki a
tun ye koko omiran wo: awon akori to se koko ninu
Kuran. Isokan Olorun Oba, oruko re, iwa re, ibasepo
laarin Olorun ati awon iseda re, ati bi o se ye ki awon
eniyan motujo ibasepo naa. Ibasepo awon annabi
ati awon ojise, ise iranse won ati ise won ni pato. Ati
itenumo Muhamadu (pbuh) gegebi akoja awon anna-
bi ati ojise. Ni riran awon eniyan leti wipe igbe aye yi
kuru ati pipe won si aye ti o wa leyin aye yi. Aye leyin
aye yi tumo si leyin ibi yi. Leyin ti o ba kuro ni ihin ti
o lo ibomiran; N o so nipa asale yi. Sugbon lehin ti o
ba ku ti o si fi aye yi sile, O n lo si ibikan, boya o gba
atabi o ko gba; On lo sibe, o si ku si O lowo nitori A
ti so fun O—bo ti e wu ki o ti koo. Nitori koko aye
yi ki ise ki o kan joko nibi yi, ati leyin eyi ko ma se
ohunkohun. Gbogbo ipa lo ni idi! O si wa si aye yi
fun Idi ati eredi kan, o si gbodo ni ipa. O gbodo ni
awon ipa kan! Ti o ko ba se ise O ko ni gba owo! Ti o
ko ba kawe o ko ni tesiwaju! Ti o ko ba dagba gegebi
omode o ko le di agbalagba! Ti o ko ba se ise o ko le
ri ere! O ko le maa gbe ile aye lai ni ireti ati ku! O ko
le ni ireti a ti ku lai ni ireti iboji! Atipe o ko si le ro pe
iboji ni gbogbo re pari si. Eyi a tumo si wipe Olorun
kan da O lasan. O ko si lo si ile iwe, o ko se ise, tabi o
ko se ohunkohun, tabi o ko fe aya, o ko so awon omo
re l’oruko ni aini idi kan pato. Bawo ni o se ma wa ro
wipe lasan ni Olorun se awon nkan tire?
Ni igbiyanju lati jere okan ati ero eniyan, Kuran
gba ona nla lati se alaye nipa ewa awon odo ati omi
nla, awon igi ati ohun ogbin, eye ati kokoro, awon
eranko buburu ati eranko kekere, awon oke nla ati
awon ogbun ile, awon ofurufu, awon irawo oju orun,
gbogbo agbaye, awon eja ati awon eranko inu ibu,
eya ara eniyan, itan iseda eniyan, apejuwe aljanna ati
ina apadi, ibi omo eniyan, ise gbogbo awon annabi ati
awon ojise, ati ere idi iwalaye ninu Aye. Ati bi omode