Page 4
The Islamic Bulletin
The Purpose Of Life
– gboran si Olorun! E josin si Olorun Atobiju ki e si
mu ere idi iwalaye yi se ati ki e se rere, a o si fun yin
ni aye miran. Eyi nikan ni won so! Ma se b pe o ju eyi
lo! Eyi nikan ni won so, edekede yi o wu ati akoko yi
owu, tabi eni ti a ran won si – Eyi nikan ni won so.
Ti e ba ka iwe mimo pelu ifarabale, lai fi itumo
ti ara re si tabi afikun lati odo elomiran tabi ero elomi-
ran – iwo yi o ri wipe eyi ni ise iranse ti gbogbo awon
anabi yi mu wa ti won si jeri ara won. Ko si eyikeyi
ninu awon anabi yi ti o wipe, “Emi ni Olorun – e maa
josin fun mi.” Iwo ki yi o ri eyi ninu eyikeyi iwe mimo
ti o wa ni owo re – yala Bibeli, tabi Torah, tabi Ma-
jemu Titun, tabi Orin Dafidi – iwo ki yi o ri ninu iwe
Kankan.Iwo ki yi o ri ninu eko anabi Kankan. Lo si ile
ni asale yi ki o si ye gbogbo oju iwe Bibeli re wo, mo
seleri fun O – iwo ki yi o ri eyokan. Nibikibi! Nitorina,
nibo ni eyi ti wa? Eyi je ohun ti o gbodo se awari re.
A le ri lati inu alaye yi pe, oro larubawa yi se
apejuwe gbogbo ohun ti awon anabi se. gbogbo won
wa won si jowo ara won fun Olorun; won pe awon
eniyan wa si odo Olorun; Won si so fun awon eniyan
lati wu iwa ododo. Awon ofin mewa ti Musa – kini
eyi? Eko Ibrahim - kini eyi? Orin Dafidi - kini eyi?
Awon owe Sulaimon - kini o so? Ihinrere Jesu Kristi –
kini O so? Kini Johanu Onitebomi so? Kini Isiaka ati
Ismoila so? Kini Muhamadu so? Ko ju eyi lo!
“A ko pa won lase ju pe kin won josin fun Olohun
lo, ki nwon fo esin mo fun U, kin won se dede ki
nwon ma gbe irun duro, kin won ma yan saka atipe
eyi ni esin ti o duro dede.”
[Kuran 98:5]
Eyi ni ohun ti Allah wi. Won ko si pase kan ju
pe ki a josin fun Allah, ka fi okan si odo Re.
Eyi si ni ona na, eyi ni ise iranse naa tooto.
Bakanna, o dara ki a ri awon anabi ati awon ojise ge-
gebi Musulumi, nitori ‘Musulumi’ je kini? Ma ro nipa
oro larubawa yi, ma ro nipa bi a ti ma npe won- ma
ro nipa Moka tabi Saudi Arabia, tabi Egypiti. Rara! Ro
nipa ohun ti oro yi ‘Musulumi’ tumo si. ‘Eni ti o yanda
ara re fun Olorun Atobiju, ti o si n gboran si awon ofin
Olorun Atobiju,’ ni idi eyi yala lona ayebaye tabi ni
ti ede – ohunkohun ti o ba yonda ara re fun Olorun
Atobiju je Musulumi!
Nitorina, ti omo ba jade ninu iya re ni akoko
ti Olorun ti yan – kini eyi? O je Musulumi. Ni igba ti
oorun ba n yipo – kini eyi? O je Musulumi! Ni igba ti
osupa ba nyipo oorun – kini eyi? O je Musulumi! Ofin
Ile – kini eyi? O je ofin Musulumi! Ohunkohun ti o ba
jowo ara re fun Olorun je Musulumi! Nitorina, ni igba
ti a ba finufedo gboran si Olorun a je Musulumi! Jesu
Kristi je Musulumi. Iya re je Musulumi. Ibrahimu je
Musulumi. Mose je Musulumi. Gbogbo awon anabi ni
won je Musulumi! Sugbon won wa si odo awon eni-
yan won, won si so orisirisi ede. Anabi Muhamadu (Ki
Alaafia Wa Pelu Re) so ede larubawa. Ati nitorina, ni
ede Larubawa enikeni ti o ba jowo ara re ti o si yonda
ara re je Musulumi. Gbogbo anabi ati ojise Olorun
Atobiju mu ise iranse kanna wa—‘E josin fun Olorun
Atobiju ki e si fi okan s’odo Re.’ Bi a ti n ye ise iranse
ikankan awon anabi ti o gbajumo yi wo, a le fi idi eyi
mule.
Ni igba ti ede aiy’ede ba wa, itenumo eke,
adapo iro ati asodun, fifi itumo ti ara eni si akosile
awon onkowe, onkotan ati eni kokan ni o ma n se
okufa eyi. Fun apeere, eje ki n fi nkankan han yin eyi
ti e ti le yewo tele. Gegebi Kristiani, mo ti yewo tele
ki n to di Musulumi ati pe… ko si ye mi. Ki lo de to je
wipe ni gbogbo Majemu Lailai, Olorun je okan soso—
Oluwa ati Oba gbogbo agbaye. Eyi si ni ofin akoko ti a
fifun Mose, ko je ki enikeni josin fun ere gbigbe kan;
tabi fi ori bale fun ohunkohun ni awon Orun, tabi ni
Aye, tabi ninu okun – Ko gba eyi laaye. Gbogbo awon
anabi so wipe Olorun kan soso ni o wa. Ni gbogbo
Majemu Lailai a ntun eyi so lai mo oye igba. Ni igba
to ya, lojiji a ni orisi eri merin – ihinrere merin ti a pe
ni Matiu, Maku, Luku ati Johanu. Matiu wo? Maku