Page 5
The Islamic Bulletin
The Purpose Of Life
wo? Luku wo? Johanu wo? Ihinrere merin ototo ti a
ko ni iwon odun meji-din-l’adota si ara won. Ko si si
eyikeyi ninu awon okunrin yi ti won ko fo wo sowopo
pelu ara won ti o so oruko baba won. Ti mo ba fun o
ni iwe igbowo jade lati banki lati san owo osun re ti
mo si ko oruko mi lai fi oruko baba mi si nje iwo yi o
gba ni owo mi? Rara, iwo ki yi o gba a… Ti olopa ba
da o duro ti o si beere fun kaadi idanimo re, ti o si je
wipe oruko re akoko nikan ni o wa lori re, nje eyi yi o
je itewogba lodo re? Nje o le gba iwe irina oke okun
pelu oruko re akoko nikan? Nje baba ati iya re fun o
ni oruko eyokan? Nibo ni itan awon eniyan ni oruko
eyokan se je ohun itewogba fun akosile, nibo? Ko si!
Ayafi ninu Majemu Titun.
Bawo ni o se le gbe igbagbo re si ori Ihinrere merin ti
a ko lati owo awon okunrin merin ti won ko mo oruka
baba won? Leyin eyi, a tun ni awon iwe meedogun
si ti a ko lati owo okunrin kan ti o je eni eke ti o n pa
awon Kristiani, ti o pon awon kristiani loju, ti o si wa
so wipe oun ri Jesu ni inu iran. A si yan gegebi Apos-
teli fun Jesu. Ti mo ba so fun o pe Hitler lehin ti o pa
awon Ju wa so wipe oun fe di eni igbala. Pe o si wa
pade Mose tabi Jesu ni ona o si wa di Ju. O si ko iwe
meedogun o si fi won kun Torah – nje awon Ju yi o
gba eyi? Rara, iwo ki yi o gba eyi. Nitorina, bawo ni
iwe merin ti a ko lati owo awon okunrin merin ti won
ko mo oruko baba won ati iwe meedogun miran ti a
ko lati owo okunrin miran—eyi si ni igba akoko ti a o
pe Olorun ni eniyan, igba akoko ti a o so wipe meta
ni Olorun, ati igba akoko ti a fun Olorun ni omokun-
rin—bawo ni awon Kristiani se gba eyi? Bawo? Ro
nipa eyi! A ko ni j’iyan nipa koko yi. N o kan fun yin
ni nkan lati ronu le lori.
Iwas’aye Anabi Muhamadu (Ki Alaafia Wa
Pelu Re) ko mu esin titun tabi igbe aye titun wa saye
bi awon miran se nso. Lodi si eyi, Anabi (Ki Alaafia
Wa Pelu Re) fi idi ise iranse gbogbo awon anabi ati
ojise to ti siwaju mule. Yala nipa ihuwasi re tabi nipa
awon ifihan ti o gba lati odo Olorun Oba. Iwe Mimo ti
Muhamadu (Ki Alaafia Wa Pelu Re) mu wa ni a npe ni
Kuran. O tumo si ‘eyi ti a ka.’ Nitori Muhamadu (Ki
Alaafia Wa Pelu Re) ko ko Kuran. Oun ko lo ko Kuran.
Enikeni ko wa lati ba ko Kuran. Ko si si eni ti o fi owo
sowopo pelu re lori eyi. Malaika Jubril ni o ka awon
oro naa fun! Olorun Oba si je ki okan re gba awon
oro naa. Okan Anabi (Ki Alaafia Wa Pelu Re) gba
ifihan yi a si ni Kuran ti a ti pamo lati opolopo odun
lai yi pada. Nje iwe miran wa ninu aye yi ti o mo ti
a ti pamo gegebi ati fihan laisi iyipada Kankan? Ko si
iwe… Kuran nikan.
Ma kan gba oro mi gbo, lo si ile ikawe ki o si
ye ohun ti a ko sile ninu iwe imo ofe ti Britanika tabi
iwe imo ofe ti agbaye tabi iwe imo ofe ti America,
tabi eyikeyi iwe imo ofe ni agbaye ti a ko ko lati owo
awon Musulumi. Ka ohun ti o ko nipa Islam, kuran, ati
Muhamadu (Ki Alaafia Wa Pelu Re). Ka ohun ti awon
ti ki I se Musulumi ko nipa kuran, Islam, ati Muhama-
du (Ki Alaafia Wa Pelu Re). Ni igba na ni iwo yi o
gbagbo pe ohun ti mo nso wa ni ki ko sile ka ri aye!
Pe Muhamadu (Ki Alaafia Wa Pelu Re) ni eniyan ti o
ni iyi julo ni itan gbogbo agbye. Ka ohun ti won ko.
Pe Kuran je iwe ti o ya ni lenu ju ninu itan agbaye! Ka
ohun ti wwon so. Pe igbe aye Islam je eyi ti o kun fun
emi!... Ko si ti I yi pada.
Iwe mimo ti Muhamadu (PBUH) gba ni a npe
ni ‘Kuran.’ Ikokan ninu awon anabi ati ojise ni o si gba
iwe mimo yi. Ninu Kurani, awon anabi yi, iwe mimo
won, itan won, ati opo ise ti a fun won ni a ko sile ni
kikun. Nje Muhamadu (Ki Alaafia Wa Pelu Re) pade
won, ba won soro, ba won jeun, ati fo wo so wo po
pelu won lati ko itan igbesi aye won? Rara, ko ba won
pade ri. Ninu Kuran, Muhamadu (Ki Alaafia Wa Pelu
Re) ni a mo si ojise Olorun ati akotan awon anabi
isaju—eyi ni ti I se ojuse re to gaju gegebi omo eniyan.
“Muhamadu ki ise baba enikankan ninu awon
okunrin nyin, sugbon (o je) Ojise Olohun ati ipekun
awon annabi. Olohun je Oni-mimo nipa gbogbo
nkan.”
[Kuran 33:40]
Awon Musulumi ki I josin fun Muhamadu. A ki
I se omo lehin ‘Muhammadu.’ A ko ni eto lati pa oru-
ko Muhamadu da ki a wipe a je omo lehin Muhama-
du. Awon ti o tele musa ki I se omo lehin Musa. Rara,
awon ti o tele Yakubu ki ise omo lehin Yakubu. Tabi
awon ti o tele Ibrahim ki I se omo lehin Ibrahim Tabi
omolehin Dafidi. …Rara, rara, rara. Nitori na, bawo
ni awon eniyan se n pe ara won ni ‘Kristiani?’ Kristi ko
pe ara re ni ‘Kristiani,’ ki lo wa de ti awon eniyan n pe
ara won ni ‘Kristiani?’
Jesu Kristi (PBUH) so wipe ohunkohun ti oun
ba gba lodo Olorun je oro Olorun, ati ohun ti oun ba
gbo ni oun n so! Ohun si ni oun nse! Nitorina, ki lode
ti awon eniyan npe ara won ni ‘Kristiani?’ A ni lati wu
iwa bi Kristi! Bawo ni Kristi ti ri? O je eru Olorun; nito-
rina a gbodo je eru Olorun.
Gegebi iwe mimo ati ifihan atokewa ti o kehin,
kurani so oro yi pelu idaniloju wipe,
“Loni yi Mo se esin yin ni pipe fun nyin ati pe Mo se
asepe idera Mi le nyin lori ati pe Mo yonu si Islam
ni esin fun nyin.”
[Kuran 5:3].
Nitorina oro naa ‘islam’ wa lati ipa se kuran.
Nitori ti a ba ti ko ile tan, aa pe ni ‘ile.’ Ni igba ti oko
ba si wa ni ile ise ti a ti n se, a ko I ti le pe ni oko,o si
wa lenu sise! Ni igba ti a ba pari re, ti a ti ye wo ti a ti
waa wo – o ti di ‘oko.’ NI igba ti Islam pari gegebi ifi-
han, gegebi iwe, bi apeere lati owo Anabi Muhamadu
(PBUH), o wa di ‘Islam.’ O di liana igbe aye.
Nitorina, oro naa ni o je titun ki I se iwa …
ki I se anabi… ki I se liana lati odo Olorun… ki I se
Olorun titun…ki I se ifihan titun… sugbon oruko titun
nikan, Islam. Bi mo si ti wi saaju, tani gbogbo awon
anabi wonyi? Gbogbo won jee Musulumi. Ohun